Obi: E kaaro, Baaba mi.
Oyedepo: Ope ni fun Oluwa, bawo ni ooo?
Obi: Mo wa daada, Baaba mi, E kaaro
Oyedepo: Amin, ni oruko Jesu, esi ayo la maa gbo?
Obi: E se Baaba mi, ti mo ba gbo ipe lati odo yin: ipe ati adura yin, Baaba mi, o je nkan to wuwo pupo fun mi. Bii mo see maa n so fun yin, ti eleyi ba ja si daada, e o ni kabamo wipe e duro ti mi.
Oyedepo: Amin, amin, a ni igbagbo wipe Olorun maa gba akoso.
Obi: E se Baaba mi. Mo fe iranlowo yin lati ba awon eniyan yin ni iwo oorun ati ipinle Kwara, awon Kristeni ni iwo oorun ati ipinle Kwara, e je ki won mo wipe ogun esin ni eleyi.
Oyedepo: Mo ni igbagbo lori eleyi. Se o mo wipe mo se atejade kan pelu akori wipe “Ilosiwaju Ile Naijiria”, mo maa gbe omiran jade loni. Sugbon ni oruko Jesu, ibi rere ni eyi maa jasi.
Nkan ti mo so ni wipe: Orile ede Naijiria nfe eniti o ni okun ati ilera, mo ni wipe eniti ibi ti o ti ni owo ati ola re sokunkun ko gbodo sun mo ibiti a ti n se ijoba.
Nitori naa, gbogbo nkan ti a n se ni wipe ki a ba awon eniyan wa soro, ki a wole si won lara ki won mo ibiti o ye ki won lo. Sugbon mo ni idanu loju wipe esi ayo ni a maa gbo.
Obi: E se pupo, Baaba mi.
Oyedepo: Nitori naa fi okan bale, ma jaya, se Eko lo wa abi Abuja?
Obi: Onitsha ni mo wa bayi
Oyedepo: Se ibe ni oo maa wa fun eto idibo?
Obi:Beeni sir
Oyedepo: Iyen daa bee, ibi ti o ye ki o wa niyen. Mo so wipe gbogbo Omo Naijiria lo ni eto si ijoba, ko si enikan ti o gbodo so wipe ohun se anfaani fun enikeji, ikan naa ni gbogbo wa.Bawo ni ila Oorun (East)ati awon Aarin gbugbun (Middle Belt)?
Obi: Ila Oorun na daada, aringbugbu naa da sugbon awon bii ipinle Kogi, Kwara ati Niger nko ni lominu.
Oyedepo: Aa maa de Ipinle Kwara.
Obi: Eleyi daa pupo! Mo lo si Ipinle Kwara, mo de odo Kaabiyesi Olofa ti ilu Offa, Kaabiyesi fi ye mi wipe Oloselu kankan ko i tii de odo awon yato si emi. Kaabiyesi so wipe ko si wahala fun mi. Mo ti de odo awon ijo Kristeni ni Ipinle Kwara ati Niger. Mo de n sise lori awon ti Ipinle Kogi.
Oyedepo: O daa bee! Awon ni mo maa dari atejade mii tuntun si, mo maa ri wipe o de odo won.
Obi: E se pupo, maa fi oju sona si atejade naa, e jowo e fi ranse si mi.
Oyedepo: Maa see bee, Olorun Aa bukun e.
Obi: E se, Baaba mi.